Oriki Osogbo In Yoruba (Oriki Ilu Osogbo)

Osogbo is a city located in Osun State, Nigeria. It is a city with a rich history and cultural heritage. Osogbo is famous for its annual Osun-Osogbo festival, which is held in honor of the river goddess, Osun. Oriki Ilu Osogbo audio mp3 is also available below.

Join Our Investment Group

Oriki Osogbo

Osogbo Oroki Asala Onile Obi

Osogbo ilu Aro, Aro dede bi Okun

Join Telegram Channel

Are Op’eta, Are p’eta a gba

Osogbo Oroki gbe Onile o tun gbe Ajeji

Osogbo Oroki Omo yeye Osun

Yeye Atewogbeja Aniyun Labebe

Eleyele Aro, Olode Ega, Ega susu ni yara

Ewure Orangun ti n je lese Gbagede

Lese Gbagede ni ti ije

Aguntan Orangun nii je lese Yara

Akuko gagara t’o rori Ope ree le tente

Nibe ni won ti n pe Alara tantan

Ogboju Obinrin tii fi owo gbogboro yo omo re lofin

Yeye Larooye t’o ti Ipole di onile losogbo

Yeye Timehin akikanju Ode t’o m’erin wa mo ilu Osogbo,

Osogbo Oroki omo Olofin agba Ife

Omo Owa Oluyeye, Omo Obokun

Omo odo kan odo kan ti won n pe losun

Omo atenigbola olodo ide

Ogun kan, Ogun kan ti won n ja loroki ile

Obinrin gbona, Okunrin ko gbodo koja

Bi Okorokoro ti n gba oko niju

Bee ni Ogbaagbaa n run bala bi ose

Opo gbegiri l’osun fi segun Fulani

Ogun ko gbogbo jami, mo gbekeleOsun

Oroki tii ba Eja nla soro, tii ran iko ni’se

Osun Osogbo rere ni’Osun funmi

Ire Owo, Ire Omo, Ire Aiku Baale Oro

Osun t’ori ajigbara, leke o bawon ni orun gigun

O’tori ide wewe o bawon lapa gbogboro

B’oba wu agba Ijesha a san’so si bebere idi

B’oba wu Morokahan a san’so Gbogbo lo itan

Osogbo Oroki t’oni lakokan l’o ni Ohuntofo

Oun loni Ogidan tii fi Odo ide fo’gun

Omo atupa merindinlogun tii tan loroki ile

B’oba tan f’oba a tan f’osun

A tun tan fun irunmole a tan f’eniyan

Osogbo wumi ide ki n lo d’agbala osun

Ni bi ti won ti n re ro ti won tun ti n gundo ide,

A kii b’omi s’ote, a kii b’omi s’ota

Omi l’a buwe, omi la bu mu

Ore yeye Osun Osogbo o.

Leave a Comment