Are you looking for oriki ibeji in yoruba, then look no further as we would be providing you with the real traditional yoruba ibeji (ejire) oriki write up with lyrics below. The is very useful for parents or relations of twins. You can praise them with this oriki. We have also provided oriki ibeji in yoruba audio download below so you can listen to it. Checkout Yoruba twins panegyric below.
ORIKI IBEJI
Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún.
Ẹdúnjobí
Ọmọ ẹdun tíí ṣeré lorí igi
Ọ́-bẹ́-kẹ́ṣé-bẹ́-kàṣà,
Wínrinwínrin lójú orogún
Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀.
Bu mì kín ba o relé
Kìmí kín pada leyin r ẹ̀
Omo ko ile alaso
Ó fẹsẹ̀ méjèèjì bẹ sílé alákìísa;
Ó salákìísà donígba aṣó.
Pekilore, ape fi se iranwo
Aitete ji onile gba ile
Ẹdun ama gbe ori igi referefe
Awodi ama gbe ojo orun keren keren
Erelu igbo
Oloju lako labo
Ode kile kun
Ode teru tẹ̀ru
Gbajúmọ̀ ọmọ tíí gbàkúnlẹ̀ ìyá,
Tíí gbàdọ̀bálẹ̀ lọ́wọ́ baba tó bí í lọ́mọ.
Wínrinwínrin lójú orogún
Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀.
Tani o bi ibeji ko n’owo?
Ẹ̀jìrẹ́ okin
Ẹ̀jìrẹ́ ti mo bi, ti mo jo
Ẹ̀jìrẹ́ ti mo bi, ti mo yó
Ẹ̀jìrẹ́ ara isokun
Omó édun nsere lori igi
Ẹ̀jìrẹ́ wo ile olowo ko ló
O wo ile olola ko ló bé
Ile alakisá lo ló
Ẹ̀jìrẹ́ só alakisá di alasó
O só otosi di olowo
Bi Taiwo ti nló ni iwaju
Bééni, Kéhinde ntó lehin
Taiwo ni omode, Kehinde ni ebgon
Taiwo ni a ran ni sé
Pe ki o ló tó aiye wò
Bi aiye dara, bi ko dara
O tó aiye wò. Aiye dun bi oyin
Taiwo, Kehinde, ni mo ki
Eji woró ni oju iya ré
O de ile oba térin-térin
Jé ki nri jé, ki nri mu
ORIKI IBEJI & EJIRE
Ejire oyila winiwini loju orogun, ejiworo loju iya re
Mba bejire mbayo, O be kese be kasa, ofese me jejeji be sile alakisa
o so alakisa di onigbaso, okan ni mba bi mba yo, sugbon meji lowole tomiwa,
Gbajumo omo ti ngba ikunle iya, ti ngba idobale lowo baba to bi won lomo
Ejire ara isokun, edunjobi omo edun tin sere ori igi
Epo nbe, ewa nbe, aya mi oja lati bi ibeji
Taiyelolu ma yo se se, Akehinde gbegbon mayo se se
Ejire oyila, ema yo se se, nbabi edunjobi mba yo pe mobi oba omo.
Edumare bawa da awon Ibeji wa si
Amin, Ase