Oriki Ilu Ife celebrates the rich heritage, mythical origins, and majestic essence of Ife as the ancestral home of the Yoruba civilization.
Ife is an ancient Yoruba city in Nigeria, is located in Osun State, about 218 kilometers northeast of Lagos. It was founded by Obatala according to Yoruba religious traditions and later ruled by Oduduwa. Ife’s first ruler, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi Ojaja II, has been in power since 2015. The city is known for its worship of 401 deities and hosts various festivals. Ife is renowned worldwide for its ancient sculptures made of bronze, stone, and terracotta, dating back to 1200-1400 A.D.c
Oriki Ile Ife 1
*ORÍKÌ ILÉ-IFẸ̀*
Ifẹ̀ oòyè lágbòò
Ọmọ olódò kan òtéréré
Ọmọ olódò kan ọ̀tàràrà
Odò tó sàn wéréké, tó sàn wèrèkè
Tó dẹ́yìnkùlé Ọṣilẹ̣̀ tó dòkun
Ó dẹ́yìnkùlé Adélawẹ̀ tó dàbàtà
Oníkẹ́kẹ́ kò gbọ́dọ̀ bù mu
Ababàjà wọn kò gbọ́dọ̀ ṣan ẹsẹ̀
Ògèdègédé onísọ̀bọ̀rọ́ ni yóò mu omi odò náà gbẹ
Sọ̣̀bọ̣̀rọ́mi wù mí, ẹ jẹ́kí ibi dandan máa bá alábẹ
Wọn kì í dúró kí wọn nífẹ̀ Ọọ̀ni,
wọn kì í bẹ̣̀rẹ̀ kí wọn nífẹ̀ oòyè
Kò ga, kò bẹ̀rẹ̀ làá kí wọn nífẹ̀ oòdáyé
Bí wọn kò sì kí wa nífẹ̣̀, wọn kì í tó abẹ́rẹ́
Ojú bíntín la fi ń wo ni
Èmi wá kí ọba nífẹ̣̀, mo lo àkún
Ọba níí lo sẹ́sẹ́ ẹfun
Adimula,
Ohun méje níí mu ilé olúfẹ̀ wù mí
Bàǹtẹ́ gbọọrọ, ní múfẹ̀ wù mí
Ṣẹ̣̀gi ọwọ́ àti tẹsẹ̣̀,
Ká fárí apá kan, ká dá apá kan sí
Yéèpà òrìṣà, aṣọ funfun
Òhun níí mú ilé olúfẹ̀ wù mí
Àpadarí ẹni, àpalàdọ̀ ènìyàn
Ẹbọ ojoojúmọ́, níí mú ilé wọn sú níi lọ
Àwa lọmọ oní fìtílà rébété
Iná kò níí kú níbẹ̀ tọ̀sán tòru
Ibẹ̀ ni baba wa gbé ń ka owó ẹyọ
Àwa lọmọ onílù kan, ìlù kàn
Tí wọn ń fawọ ẹkùn ṣe
Aketepe etí erin ni wọn fi ń ṣe ọsán rẹ
Oníkẹ́kẹ́ kò gbọ́dọ̣̀ jó o
Ababàjà kò gbọ́dọ̀ yẹsẹ̣̀
Kìkìdá onísọ̀bọ̀rọ́ ni yóò jó ìlù náà ya